Isaiah 35
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ayọ̀ àwọn ẹni ìràpadà
35 Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn;
aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná.
Gẹ́gẹ́ bí ewéko,
2 Ní títanná yóò tanná;
yóò yọ ayọ̀ ńláńlá yóò sì kọrin.
Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un,
ẹwà Karmeli àti Ṣaroni;
wọn yóò rí ògo Olúwa,
àti ẹwà Ọlọ́run wa.
3 (A)Fún ọwọ́ àìlera lókun,
mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun:
4 Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé
“Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;
Ọlọ́run yín yóò wá,
òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san;
pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́
òun yóò wá láti gbà yín là.”
5 (B)Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú
àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.
6 Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín,
àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀.
Odò yóò tú jáde nínú aginjù
àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.
7 Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà,
ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi.
Ní ibùgbé àwọn dragoni,
níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀,
ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.
8 Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀:
a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà Mímọ́.
Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà;
yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà,
àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.
9 Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀,
tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀;
a kì yóò rí wọn níbẹ̀.
Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,
10 àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin;
ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí.
Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn,
ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.